Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé iṣẹ́ tí ń mójútó Ìrìn àjo lọsí orílẹ̀-èdè mìíràn dá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Mali méjìlé-lọ́gọ́ta padà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

66

Ilé iṣẹ́ tí ń mójútó Ìrìn àjo lọsí orílẹ̀-èdè mìíràn ní Nàìjíríà (NIS), Aala Agbofinro Illela ti ipinlẹ Sokoto, ti fidiẹ mulẹ pe wọn ti dá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Mali méjìlé-lọ́gọ́ta padà lati oju ile Illela.

Adari Ikọ naa, Ọgbẹni Tony Akuneme, sọ ninu alaye kan ti o fi sita ni ọjọ Aiku ni Abuja, o ni  awọn eniyan naa jẹ ọkunrin mọkanle-laadọta ati obinrin mọkanla.

Akuneme ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ mẹjọ ti ọgbẹni Mamoud Sadiq ṣoju, ninu ọkọ meji ni o tẹle awọn ọmọ orilẹ-ede Mali naa lati olu ile iṣẹ ni NIS, lati Abuja lọ si aala Illela ni Sokoto.

O ni ikọ naa gunlẹ si oju ile aala naa ni bii agogo mẹjọ alẹ, ni ọjọ Ẹti.

 

Comments are closed.

button