Ìgbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Kashim Shettima tí ké sí àwọn Olóṣèlú ní ìpínlẹ̀ Kano, Ìwọ̀-oòrùn Àríwá Nàìjíríà láti gbá àlàáfíà láàyè kó jọba ní Ìpínlẹ̀ náà.
Shettima ṣé ìpè yìí l’àkókò tó ṣé àbẹwò ìtùnú sí ìdílé Galadinma Kano, Alhaji Abbas Sanusi, tó kú láìpẹ́ yìí.
Ìgbákejì Ààrẹ náà sọ pé òún rọ́ àwọn olóṣèlú náà láti má jẹ́ kí òṣèlú ẹlẹyamẹya pín wọ́n yẹlẹ-yẹlẹ, Ó sọ́ èyí ní ilé olóògbé náà.
Ó sàlàyé pé “ Ìpínlẹ̀ Kano ní ọkàn àríwá tí òún sí wá láti Àríwá náà”, Ó wá ń gbá làdúrà pé, “Kí Ọlọ́run Allah mú ìsọkan wà láàárín wà.”
Nígbà tó n sọrọ tẹlẹ, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kano, Abba Kabir Yusuf dúpẹ lọ́wọ́ Ìgbákejì Ààrẹ lórúko ìjọba ìpínlẹ̀ náà àti àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Kano.
Comments are closed.