Ẹgbẹ́ Aláàdáni tí wọn pẹ ni (SUNDAYI) ti Victoria Jim jẹ aṣojú fún ti bere fún atilẹyin àti ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọ tó ni àìsàn Autism.
Ó sọ èyí di mímọ̀ ni ìlú Abuja nígbà tí wọn ṣe ìpàdé, wọn sàlàyé pàtàkì tí o wa nínú ìbáṣepọ̀ pẹ́lù àwọn ènìyàn láti ṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn ènìyàn tó ni àìsàn náà.
Jim ni gbogbo àwọn tó ni àìsàn Autism ni o ní ètò sí ìwòsàn ọfẹ, ètò ẹkọ àti ìbáṣepọ̀ pẹ́lù àwọn ènìyàn.
Ó ní àwọn ti ṣetán láti ṣe àtúnṣe láti fi òpin sí àlàfo sí bi àwọn ènìyàn ṣe n ṣe sí àwọn tó ni àìsàn náà.
Ó ní ó ṣe pàtàkì bí wọn bá lẹ ma gba wọn láyé láti kópa nínu ètò ìlú