Ilé Asòfin Se Àtìlẹyìn Fún Ìgbésẹ̀ Ààrẹ Látàrí Ìkéde Ìjọba Pàjáwìrì Ní Ìpínlẹ̀ Rivers
Ilé ìgbìmọ̀ Asòfin kejì ti buwọ́lu ìgbésẹ̀ Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu pẹ̀lú ìkéde ìjọba pàjáwìrì tí ó wáyé ní ìpínlẹ̀ Rivers
Wọ́n se àtìlẹyìn fún ìgbésẹ̀ náà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gba ìwé àtẹ̀jísẹ́ èyí tí ó ń bèrè fún ìbuwọ́lù ilé asòfin ní Ọjọ́bọ̀
Asojúsòfin Ali Isa ni ó se agbátẹrù àbádòfin náà léyìí tí ó pè fún mímú àdíkù bá gbèdéke osù mẹ́fà tí Ààrẹ kéde, sùgbọ́n ní kété tí àlàáfíà bá ti jọba, kí ìjọba pàjáwìrì náà kásẹ̀ nílẹ̀ tí ìjọba tiwa-n-tiwa yóò sì padà sípò ní pẹrẹwu, léyìí tí asojúsòfin Miriam Onuaha sì kéjì àbá náà pẹ̀lú ìfọwọ́sí àpapọ̀ gbogbo ilé
Ilé asòfin wá pè fún yíyan ìgbìmọ̀ apẹ̀tùsááwọ̀ láti dá àlàáfíà padà sí ìpínlẹ̀ Rivers àtipé ilé asòfin àpapọ̀ ni yóò máa darí ètò òfin àti àbádòfin ní ìpínlẹ̀ Rivers láàrin gbèdéke osù mẹ́fà tí ìjọba pàjáwìrì náà yóò fi wáyé