Take a fresh look at your lifestyle.

Ayò Oníbẹta Tí Fernandes Gbá Wọlé Fún Ikọ̀ Manchester United Pa Ikọ̀ Real Sociedad Lẹ́nu Mọ́

135

 

Ògbóntàrigì agbá bóòlù ní ipò àárín ọmọ Portugal Bruno Fernandes gbá ayò mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Wọlé bí ikọ̀ Manchester United ti pa ikọ̀ Real Sociedad lẹ́nu mọ́ pẹ̀lú ayò mẹ́rin sì oókan [4-1].
Èyí jẹ kí wọn peregede fún ipele kòmọẹsẹ̀óyọ Líìgì Europa ni Old Trafford ni Manchester, England.

Ògbóntàrigì gbá ayo àkọ́kọ́ wọlé pẹ̀lú ayò golí wòó kí n gba sí ọ[Penalty], O gba èkejì wọlé bakanna bí o ṣe se ní àkọ́kọ́, O tún gbá ẹkẹta wọlé nigba ti àwọn alátakò wọn kù mẹwa lórí pápá kí Diogo Dalot tó wá f’oba leè. O wà yori Si marun sí meji [5-2] ní àmìpọ̀ ìdíje àkókò àti elekeji. Fernandes sọ eyi nigba ti wọn ní f’ọrọ wà lẹnu wò.

Ikọ̀ Manchester United yóò koju Olympique Lyonnais ni ipele eleni mẹjọ tó kú, iko Faranse náà lu Steaua Bucharest ní alubami ayo merin sì ofo[4-0] ,iko Rangers náà lu Fenerbahce pẹlu ayò mẹta sí meji[3-2] ní ibi ayo goli wòó kí n gba si ọ[Penalty] leyin omin ayo mẹta sí mẹta àmì papọ̀

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button