Alága Ẹgbẹ́ àwọn elétò ìlera ẹka ti ìpínlẹ̀ Ebonyi, Chetachi Usulor ti gbósùbà fún gómìnà Ìpínlẹ̀ Ebonyi, Francis Nwifuru látàrí akitiyan rẹ̀ lórí ìdàgbàsókè ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ náà
Usulor lu gómìnà lọ́gọ ẹnu látàrí ìgbàṣíṣẹ́ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ elétò ìlera tí ó lé ní ọ̀ọ́dúnrún, ó sàpèjúwe ìgbésẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí yóò mú ìdàgbàsókè bá ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Ebonyi
Ó tẹ́ pẹpẹ àlàkalẹ̀ ìjọba láti se àmójútó ìtọ́jú àwọn ògo wẹẹrẹ àti àtúnṣe ilé ìwòsàn gbogbo èyí tí yóò mú àyípadà bá ẹka ìlera