Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra, Ọ̀jọ̀gbọ́n Chukwuma Charles Soludo ti gbósùbà fún ìfàdúràjagun Dunamis tí ó wáyé ní gbọ̀ngàn Dokita Alex Ekueme, ní Awka
Ètò náà kẹ́ṣẹ járí látàrí bí ó se wáyé ní ìrọwọ́-rọsẹ̀ léyìí tí kò dí ìgbòkègbodò ọkọ̀ àti ènìyàn lọ́wọ́
Gómìnà fi ìdùnnú rẹ̀ hàn látàrí bí ètò náà se wáyé, ó sì se ìrànlọ́wọ́ owó fún ìjọ Ọlọ́run, ó sì pé fún àkọ̀tun irúfẹ́ àdúrà bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ iwájú