Àjọ Jamb ti tilẹ̀kùn ìforúkọsílẹ̀ (2025 Unified Tertiary Matriculation Examination (UTME)) fún ìdánwò Jamb fún àwon akẹ́kọ̀ọ́ fún ti ọdún 2025 láti wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga.
Ètò ìforúkọsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta osù Kejì níbití akẹ́kọ̀ọ́ tó lé mílíọ̀nù Méjì (2,030,627) ti forúkọsílẹ̀ ti yóò sì fún wọn ní anfààní láti ṣe ìdánwò náà ní ọjó karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún, 2025
Àwọn iye tó forúkọsílẹ̀ sílẹ̀ yii yàtọ̀ sí àwọn ti wón yóò ṣe ìdánwò tiwọn ní gbọ̀ngán ìdánwò ní ilẹ̀ òkèèrè.
O ju igba ẹgbẹ̀rún ó lé díẹ̀ (200,115) akẹ́kọ̀ọ́ ló fi ìfẹ hàn sí ìdánwò ìdánrawò tí wọn npè ní mock UTME ti yóò wáyé ní ọjọ́ karùn ún oṣù kẹrin ọdún yìí fún ìgbáradì ojúlówó ìdánwò náà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san