Take a fresh look at your lifestyle.

Iyaafin Soludo, Àjọ NAWIS Sowọ́pò Lórí Ìlera Àwọn Obìnrin Pẹ̀lú Eré Ìdárayá

200

 

Ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra, iyaafin Nonye Soludo, ti ke gbajari fún ìlera pípé nipasẹ sise eré ìdárayá ati yiyan láàyò igbesi aye àlàáfíà fún aráyé. O sọ eyi nibi Ipade pẹlu àjọ Anambra Chapter of the Association of Nigeria Women in Sports (NAWIS) nibi gbọ̀ngán
ilé ìdésí ti gómìnà ní ìlú Amawbia, Awka.

Ní àkókò àbẹwò, iyaaf6 Soludo múlele rẹ pe wiwa asiko fún eré ìdárayá ati jijẹ oúnjẹ tó ṣe ará lóore dara fún ìlera àwọn obìnrin. ” Akoko niyi láti gbajumọ eto ilera wa”, o sọ eyi.

Iyaafin Soludo tún rọ awon iya láti mójú tó àwọn ọmọ wọn obinrin, kí wọn je olufẹ wọn ,kí wọn ma gba ewu tó wà ninú ẹrọ ayelujara láti bá aye ọmọ wọn jẹ́.

O wà gboriyin fún akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ bọọlu alafowogba volleyball fun akitiyan rẹ, o tún gba àjọ NAWIS nimoran àti koriya láti jẹ kí eré ìdárayá tẹẹ siwaju laarin àwọn obìnrin.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button