Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers ti sọ pàtàkì bí àlàáfíà ṣe se pàtàkì àti bí àlàáfíà ṣe ní láti máà tẹẹ siwaju pàápàá jùlọ ní àkókò ipenija oloselu yìí.
Nígbàtí ó n sọrọ níbi ìfilọ́lẹ̀ ààfin tuntun ti alálẹ̀ Nyeweali Akpor àti ilé ibugbe ọba Eze Levi Amos Oriebe, Gómìnà Fubara fi dá àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ náà lójú pé wọn yóò la gbogbo ìṣòro yòówù kí wọ́n leè máa la kọja, wọn o sì borí dandan ní, àwọn ènìyàn yóò sì tun wà ní ìṣọ̀kan ju ti ateyin wá lọ.
O tún sọ pé ìjọba òun ní ètò amúlúdàgbà tó dára lọkàn fún ìgbádùn mùtúmùwà àti fún ìdàgbàsókè wọn àti ìlú.
Ó wá dúpẹ lọwọ àwọn ènìyàn
Akpor Kingdom fún dídá oun lọ́lá pẹ̀lú ewé oyè tí wọ́n jálé òun lórí, ó fi dáwon lójú pé ipinlẹ náà yóò gòkè agba.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san