Take a fresh look at your lifestyle.

Wọ́n Sọ Ọmọ Orílẹ̀-èdè China Méjì Sẹ́wọ̀n Látàrí Ìwakùsà Ní Ọ̀nà Àìtọ́ Ní Ìpínlẹ̀ Kwara

163

 

Adájọ Ilé ẹjọ́ tó ga julọ ni orílẹ̀-èdè tó kalẹ si ìlú Ìlọrin, Abimbola Awogboro ti sọ ọmọ
Orílẹ̀-èdè China Méji Yang Chao ati Wu Shan Chuan si ẹ̀wọ̀n fún ẹsun Iwakusa ohun alumọni ní ọnà aitọ́ ní ìpínlẹ̀ Kwara.

Wọn dáwọn lẹjọ pẹlu Ile ise wọn Crius Chemical Nigeria Limited. Àwọn méjèèjì sì ti gbà pé àwọn jẹbi ẹsun ri wọn fi kan wọn. Adájọ́ ti sọ wọn sì ẹwọn ọdún méjì tàbí kì ẹni kọọkan wọ́n san owó ìtanràn Mílíọ̀nù kan Naira. Ki Ile ise wọn náà sì san Mílíọ̀nù kan Naira pẹlú.

Ní àfikún pelu idajọ wọn, wọn o tun san Mílíọ̀nù mọkanla náírà fún ijọba àpapọ, gbogbo ohun alumọni tí wọn bá ṣi bà ní àwùjọ ilé iṣẹ won ni No. 1, Idi Ope Road, ni ona,Ogunmakin-Odede Road, Omi, Ipinle Ogun lo ti di ti ijọba.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button