Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù obìnrin Nàìjíríà, Super Falcons dúró tipọ́n nípò wọn tíwọ́n wà nipa wíwà ní ipò kẹrìndínlógójì lágbayé.
Olùborí nígbà mésàn án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ilẹ̀ Áfríkà dúró sí ipò yìí láti oṣù kẹta, ọdún 2024. Wọ́n sì tún wà níbẹ̀ ní osù kefa, keje àti oṣù Kejìlá ọdún kan náà. Wọ́n sí wà nì ipò àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.
Àwọn tó tele wọn ni; ikọ̀ South Africa ti Ife ẹ̀ye Ilẹ̀ Adúláwọ̀ (Women’s Africa Cup of Nations (WAFCON)) wà lọ́wọ́ wọn, wọn wà ní ipò kẹrìnléláàdọ̀ta lágbayé, ikọ̀ Morocco wà ní ipò Ọgọ́ta lágbayé, Zambia – ipò kẹrìinlélọ́gọ́ta àti Ghana tẹ̀lé wọn ni ipò kàrùnlelọ́gota lágbayé.
Ikọ̀ àwọn obìnrin USA ló wà lókè ténté tó dára jù lágbayé pẹ̀lú ikọ̀ Olúborí lágbayé, Spain, Germany, England àti Japan ni sísẹ̀ntẹ̀lé.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san