Obìnrin àkọkọ , Oluremi Tinubu ti mọ rírì àti ipa ribiribi ti àwọn obìnrin kó fún orílẹ̀-èdè fún ìtẹ̀síwájú rẹ̀. Ó tẹnumọ èyí pé, obìnrin ni ipa pàtàkì láti kó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka láti leè mú kí orílẹ-èdè dàgbà àti kí o tẹ́ẹ̀ síwájú.
Ó sọ eyi níbi ìfòròwánilẹ́nuwò pẹ̀lú oníròyìn ni gbọ̀ngàn ààrẹ ni àyajo ọjọ́ àwọn obìnrin lágbayé ti ọdún 2025
Ìyáàfin Tinubu rọ àwọn obìnrin láti máṣe rẹ̀wẹ̀sì nípa mímú ki àlá wọn wa sí ìmúsẹ̀.
“Ààyè nìyí láti sọ pé ẹ kú ayẹyẹ obìnrin lágbayé’. Àkòrí rẹ̀ dá lórí ìpàdé Beijing, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún. Kíni a se gẹ́gẹ́ bí Obìnrin?
“Ẹ̀yin obìnrin, mo yọ̀ fún yín, ẹ máa se nǹkan tó yẹ kẹ́ se, ẹ gbé orí yín sókè, ẹ kú ọdún ayẹyẹ àwọn obìnrin lágbayé’ “, ó sọ èyí.
Obìnrin àkọkọ fi kun pé, òun ní ìgbàgbọ́ pé àwon ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè yìí ni àwọn nǹkan àmúyẹ láti gòkè àgbà.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san