Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ti bèrè fún ẹtọ ni Aarin Gbungbun Ile Olominira-Central African Republic (CAR) lẹyin ọpọlọpọ ìtẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀ ti àwọn agbofinro se. Ọ́fíìsì ajọ UN to n ja fún ẹtọ Omoniyan àti MINUSCA ti eleto alaafia mu lélé rẹ pe o se pàtàkì láti ma fí ẹtọ ọmọnìyàn dùn wọn láti dẹkun irufẹ iwa bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Iroyin rio pé ikọlu méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lo wáyé ọkàn ni Mbomou àti ekeji ni Haut-Mbomou ni osù Kewa ọdún 2023 ti o kere tan ènìyàn merinlelogun ti jáde laye pelu ipaniyan ti o lọwọ ikọ̀ The Wagner Ti Azandé (WTA) nínú pẹ̀lú ọmọ ogun àpapọ to jẹ aṣáájú rògbòdìyàn. O tun ni ọwọ ikọ̀ Azandé Ani Kpi Gbé nínú pelu, ìkọ ọmọ ogun oníhámọ́ra.
Bí agbenuso àjọ àgbà Kọmísọ́nà Iṣọkan Agbaye fún ẹtọ ọmọnìyàn, Thameen Al-Kheetan se sọ, iko adihamora ogun ti o ni àjosépò pẹ̀lú àwọn ologun fojú sun agbegbe Musulumi, alátìpó ilẹ̀ Sudan àti àwọn ti wọn nwa ibi ti wọn o ba sí.
Ẹ̀sùn burúkú ti o ni àkọsílẹ bíi ìfipábánilòpọ̀, ìfipábánilòpọ̀ eleniyan púpọ̀, ifipa fini sisẹ́, ifiyajeni alailaanu, ìwà ẹranko, itọju ẹni alábùkù, kíkó ilé àti ọjà ló ń wáyé.
Àjọ àgbà Kọmísọ́nà ìṣọkan àgbayye fún ẹtọ ọmọnìyàn, Volker Türk fẹ́ ìdájọ́ òdodo látàrí ìhùwà àwọn àjọ WTA àti àsopọ rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ogun àpapọ.
CAR ti jẹ̀yà púpọ̀ lọwọ rukerudo àti ipanle lati ọjọ to ti pẹ́, ookan ninu márùn ún ni o ti di isansa ati alarinkiri látàrí rogbodiyan to bẹ́ sílẹ̀ to n lọ lọwọ. Wahala náà ti ba ile iwe, ile iwosan àti ohun amayedẹrun to se pàtàkì jẹ́.
Ní ìdáhùn sí ìpáǹle to ṣẹlẹ yì, àjọ MINUSCA ti sá ipa to le bi awọ erin láti doola emi àwọn ènìyàn ki wọn sí tun jẹ ki ogun ko mi, ki àlàáfíà leè jọba ati aṣẹ láti odo àwọn aláṣẹ leè múlẹ ni agbègbè ti ọ̀rọ̀ kàn.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san