Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ Ẹgbẹ́ Àgbẹ̀ Yan Tarnongu Bí Adarí Ti Ìpínlẹ̀ Benue

81

 

Àjọ ẹgbẹ àgbẹ̀-National Executive Council of the Federation of Agricultural Commodity Association of Nigeria (FACAN) ti buwọ́lu ìynsípò ọ̀gbẹ́ni Vitalis Tarnongu gẹ́gẹ́bí adarí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Benue.

Ìynsípò rẹ̀ wáyé nínú lẹta ti alága àpapọ̀ àjọ FACAN, ọ̀gbẹ́ni Sheriff Balogun, FACAN buwọ́lù tó hàn sí àwọn oníròyìn ni ọjọ́ Ọjọ́bọ̀ ni ìlú Makurdi. Lẹ́tà fihàn pé ọ̀gbẹ́ni Tarnongu yóò máa darí àwọn alága àjọ ẹgbẹ́ àgbè ni ìpínlẹ̀ náà.

Ìwé náà tún sọ pé yóò máa darí gbogbo ìse ẹgbẹ́ awọn olùtajà láti rí pé iṣe nǹkan ọ̀gbìn tó dára, irè oko to yanrantí
àti iye ti wọn ńtà wọ́n, ìṣe wọn, ọjá pẹlú títà wọ́n dára.

Ki wọ́n tó yàn sípò, ọ̀gbẹ́ni Tarnongu jẹ́ alámójútó ẹgbẹ́ Eree(ẹwà)/ Cowpea ipinlẹ Benue.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button