Olùdarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, Aṣòfin Mojisola Meranda ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ nígbà Olùdarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà tẹ́lẹ̀ gba ipò náà padà, ó sì padà sí ipò Ìgbákejì Olúdarí Ilé tó wà tẹ́lẹ̀.
Wọ́n dìbò yan Aṣòfin Meranda ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méje sẹ́yìn lẹ́yìn tí wọ́n yọ Olúdarí tẹ́lẹ̀, Aṣòfin Mudashiru Ọbasá látàrí àwọn ìwà tí kò tọ́.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Aṣòfin Ọbasá dúpẹ́ lọ́wọ́ Aṣòfin Meranda àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Aṣòfin tó kù fún àtìlẹyìn wọn pàápàá nígbà tí ó kojú Ìpèníjà láìpẹ́. Ó wá ṣe ìlérí àti ṣe ìṣe olórí tí yóò ní ìfẹ́ àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Èkó lọ́kàn.
Ní àfikún, Aṣòfin Tèmítọ́pẹ́ Adéwálé ni wọ́n fi sí ipò Olórí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tó pọ̀ jù lọ nínú Ilé, nígbà tí Aṣòfin Adémọ́lá Kasunmu jẹ́ ìgbákejì rẹ̀. Aṣòfin Mojeed Fatai ló jẹ́ Ọlọ́pàá Ilé, nígbà tí Aṣòfin Setonji David jẹ́ ìgbákejì rẹ̀.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà gbóríyìn yìn fún iṣẹ́ akíkanjú gẹ́gẹ́ bí Olórí rere nínú sáà rẹ̀.
Lánre Lágada-Àbáyọ̀mí