Ikọ̀ Kano Pillars FC ti lu ikọ̀ tó wá déwọn lálejò pẹ̀lú ayò méjì sí oókan (2-) ni pápá ìseré Sani Abacha ni ìlú Kano nínú idije Nigeria Premier Football League (NPFL) ayo ọjọ ketadinlogbon.
Akọ́nmọ̀ọ́gbá ikọ̀ Super Eagles, Eric Chelle náà jẹ òkan lára èrò ìwòran níbi ìdíje náà.
Bashiru Usman láti ikọ̀ Rangers ló kọ́kọ́ yẹlé wò pẹ̀lú ayò golí wòó kí n gba síọ (Penalty) ní abala àkọ́kọ́ ìdíje náà ni iṣẹ́jú mẹ́tàlélọlọ́gbọ̀n ki Balógun ikọ̀ Kano Pillars tó dáa padà pẹ̀lú Penalty ni iṣẹ́jú méjìlélógójì, èyí jẹ́ ayò kọkànlá tí yóò gbá wọlé ni sáà yìí.
Ẹ̀wẹ̀, ní abala Kejì eré ni iṣẹ́jú ọgọ́ta, Jerry Alex fi orí gbé bọ́ọ̀lù tí Abdullahi Ali gbá síi wọlé ni ayò wá di méjì sí ẹyọkan (2-1) ti àwọn olólùfẹ́ wọn sí fò fáyọ̀.
Pẹ̀lú àṣeyọrí yìí, ikọ̀ Kano Pillars ti sún sí ipò kẹrin lórí àkàbà NPFL pẹ̀lú àmì méjìlélógójì nínú ayo mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, ikọ̀ Rangers tẹ̀lẹ́ wọn ni ipò karun ùn pẹ̀lú àmì mọ́kànlélógójì.
Nínú ayò tó ń bọ̀, ikọ̀ Kano Pillars yóò koju ikọ̀ Kwara United ni Ìlorin ni ọjọ Àìkú, ikọ̀ Rangers yóò kojú ikọ̀ Akwa United ni ọ̀nà láti ní àmì ayò tó pọ̀.
Èsì àbájáde ìfagagbága Ọjọ́ àìkú nìyí:
Abia Warriors (oókan sí ookan) 1-1 Nasarawa United
Bayelsa United (Eeji sí Eeji) 2-1 Bendel Insurance
Kano Pillars (Eeji sí ookan) 2-1 Rangers International
Niger Tornadoes (Oodo sí oókan) 0-1 Enyimba
Ikorodu City (Eeji sí Oodo)2-0 Heartland
Remo Stars (Oókan sí Oodo)1-0 Plateau United.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san