Take a fresh look at your lifestyle.

Akọ́nimọ̀ọ́gbá Ikọ̀ Manchester City Ní Ìrètí Pé Rodri Yóò Pàdà Sínú Ikọ̀ Kí Sáà Tó Tẹnubọpo

103

 

Akọ́nimọ̀ọ́gbá Ikọ̀ Manchester City, Pep Guardiola ti nírètí àti inú dídùn pé olùborí Ballon d’Or, Rodri yóò pàdà darapọ̀ mọ́ Ikọ̀ kí Sáà tó parí.

Ọ̀gbẹ́ni Guardiola ti kọ́kọ́ sọ ìrètí nù lórí ògbóntàrigì agbábọ́ọ̀lù náà torí ìfarapa tó ní sùgbọ́n bàyìí ó ti ń se ìgbáradì ẹlẹ́nikan lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tó se láti padà sórí pápá fún bọ́ọ̀lù gbígbá.

“Kìí se inú ẹ̀yin olólùfẹ́ wa nìkan ló dùn fún ipadàbọ̀ rẹ̀, Guardiola sọ eyi fún àwọn oníròyìn kété lẹ́yìn ti wọ́n lu akẹgbẹ́ wọn Plymouth Argyle ni ayò mẹ́ta sí oókan (3-1) láti dé ipele kẹrin sí àsekágbá ìdíje FA Cup. ” Ó fẹsẹ̀ kan bọ́ọ̀lù ní òní, ó ní ìgboyà ó sì tún ní ayọ̀, n kò tilẹ̀ rokàn rẹ̀ pé yóò tètè máa gbaradì, bóyá yóò tilẹ̀ rànwá lọ́wọ́ nínú ìdíje Premier League, sùgbọ́n a kò ní kánjú nínú lílò rẹ̀ kí a má bàá se àsìse”.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button