Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ AIU Sọ Fún Ehoro Orí Ọ̀dàn Ọmọ Bíbí Kenya, Kipkorir Láti Lọ Rọ́kú Nílé Fún Ìgbà Kan

193

 

Ehoro orí ọ̀dàn ọmọbíbí ilẹ Kenya, Brimin Kipkorir ní wọ́n ti sọ fún kí ó lọ rọ́kú nílé fún Igba kan náà látàrí pè ō lulèẹ̀ ìdánwò mímu ògùn olóró tí wọ́n se fun. Àjọ Athletics Integrity Unit (AIU) ló sọ èyí.

Ọgbẹni Kipkorir gba àmì ẹ̀yẹ eré sisá Onibùsọ̀ tó pọ̀ jùlọ ní orílẹ̀-èdè Sydney ní ọdún, 2024 ní wákàtí meji o lé iseju mefa pẹlu winiwini méjìdínlógún pẹ̀lú orire tó tún ṣe ní orile-ede Frankfurt ní ọdún 2022 àti 2023 níbi eré sisá ẹlẹ́mìí bákannáà.

Àjọ AIU gbé òté lé Brimin Misoi Kipkorir ọmọ ilẹ̀ Kenya fún lilo ògùn olóró tí wọn ti gbésẹ̀ lé – Presence/Use of Prohibited Substances (EPO, Furosemide).

Ẹ̀sùn nipa eré sisá yìí wọ́pọ̀ ní Kenya, gẹgẹ bí wọn se gba àmì ẹ̀yẹ ọdún 2021 eré ìje ti Boston padà lọ́wọ́ Diana Kipyokei ti ṣe ọmọ bíbí kenya nígbà tó lùgbàdí ẹ̀sùn kan náà ní ọdún 2022 tí wọ́n ṣí gbé òté ọdún mẹ́fà lée kó má leè kópa nínu eré ìje sisá.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button