Take a fresh look at your lifestyle.

Akọ́nimọ̀ọ́gbá Bú Lookman

101

 

Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Atalanta, Gian Piero Gasperini ti sọ pé ògbóntarigì agbábọ́ọ̀lù sáwọ̀n ọmọ Ilẹ Nàìjíríà ni, Ademola Lookman ni mùsè músè rẹ̀ kò dá músé músé níbi ki á gbá ayò golí wòó kí n gba síọ.

Ó sọ ayò nù tí o sì jẹ́ kí ikọ̀ Club Brugge borí pẹ̀lú Ayò mẹ́ta si oókan (3-1) nínú ìdíje UEFA ni ọjọ́ ìṣẹ́gun ní Ilé wọn.

Lookman gbá ayò ẹyọkan dondon wọlé ní ìbẹ̀rẹ̀ abala Kejì ṣugbọn èyí kò tó láti pa àwọn akẹgbẹ wọn lẹ́kún nítorí wọn ṣubú pẹ̀lú àpapọ̀ ìdíjé méjèèjì pẹ̀lú ayò màrún sí méjì (5-2).

Gasperini kabamo pe Charles De Ketelaere tàbí Mateo Retegui ni ìbá ti gbá bọ́ọ̀lù golí wòó ki n gba si ọ náà. Nítorí Ademola Lookman kò dára tó nínú ayò golí wòó ki n gba si ọ. Akọ́nimọ̀ọ́gbá Gasperini tún dá ọ̀gá agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Atalanta, Rafael Toloi, lẹ̀bi bí wọ́n se fi káàdì pupa lée jáde tèfètèfè lórí pápá látàrí àṣìṣe àti àsìsọ.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button