Òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti lu Gómìnà Seyi Makinde lọ́gọ ẹnu nígbà tí wọn fi ìdùnnú wọn hàn sí owó ìfẹ̀yìntì tó n jẹ sísan lásìkò.
Àwọn Òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì jákèjádò Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ náà lo ko ara wọn jọ sí Ofiisi Gómìnà to kalẹ Si agbègbè Agodi, ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà, láti fí ìdùnnú wọn hàn sí Gómìnà latari bí o ṣe ṣe àgbéyẹ̀wò owó ìfẹ̀yìntì wọn.
Àwọn Òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì lábẹ́ àbùradà Ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì Orilẹ Èdè Nàìjíríà (Nigera Union of Pensioners, NUP) ẹka ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ti sọ di mímọ̀ pé àgbéyẹ̀wò owó náà ti fi àwọn Òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì náà sì ìpele àwọn to n gba owó tó pọ̀ jùlọ ní Orílé èdè Nàìjíríà.
Àwọn Òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn lórúkọ Alága rẹ̀, Waidi Oloyede àti Akọ̀wé ẹgbẹ́ náà, Sunday Akin lu Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́gọ ẹnu fún bí o ṣe fi sọ owó Òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì to kéré jù di ẹgbẹ̀rún Mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n Náírà (N25,000), ẹkùn owó ìdá mẹtalelọgbọn nínú ìdá ọgọrun (33%) ni ọdún 2010, àgbéyẹ̀wò to tun dé bá owó wọn ní ọdún 2019 àti àfikún owó fún gbogbo Òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì jákèjádò Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Bákan náà ni Alága àwọn Òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olusegun Abatan gbe òṣùbà káre fún Gómìnà Seyi Makinde fún bí ṣe mú ayípadà ọtun dé bá gbogbo wọn.
Abiola Olowe
Ìbàdàn