Ìgbáyégbádùn Àwọn Òsìṣẹ́ Jẹ Wá Lógún- Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Fi Ìdí Ọ̀rọ̀ Múlẹ̀
Igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Kashim Shettima ti sàfihàn ìgbáradì ìjọba láti gbé ìgbésẹ̀ èyí tí yóò so èso rere fún àwọn òsìṣẹ́ ìjọba, ètò ọrọ̀ ajé tí ó yarantí, àlékún owó osù, àtipé ìgbáyégbádùn òsìṣẹ́ jẹ́ àkólékàn ìjọba
Ó sọ ọ̀rọ̀ náa níbi ìpàdé kan tí ó wáyé ní Ọjọ́bọ̀ pẹ̀lú àwọn ikọ̀ kan tí alákòsóo àgbà fún àjọ òsìṣẹ́ ti àgbáyé, Ọ̀gbẹ́ni Gilbert Houngbo kó sòdí, tí mínísítà Ọ̀rọ̀ Òsìṣẹ́ àti ìgbanisíṣẹ́, Alhaji Muhammad Dingyadi náà sì péjú síbẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí igbákejì ààrẹ se sọ, Aarẹ Tinubu ni àfojúsùn rere fún àwọn òsìṣẹ́ àtipé ìgbáyégbádùn àwọn òsìṣẹ́ jẹ ìsejọba rẹ̀ lógún