Take a fresh look at your lifestyle.

Erín Wo: Makinde Kẹ́dùn Adarí Afẹ́nifẹ́re, Olóyè Ayọ Adebanjọ Tó Papòdà

87

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti kẹ́dùn ikú adarí ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re, Olóyè Ayọ Adebanjọ, nígbà tó fi ikú rẹ̀ wé ìrókò nla to ṣubú ni ijù.

Makinde, ẹni tó fi ìpapòdà Olóyè Adebanjọ we òpin sáà kan, tó sì fi oloogbe náà wẹ ẹni nlá, olootọ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà rere, ẹni tó fi gbogbo ìní rẹ̀ lélẹ̀ fún ire Orílẹ̀ ède yìí.
Bákan náà ló ṣàlàyé pé, olóògbé náà jẹ́ baba fún gbogbo ènìyàn.

Gómìnà Makinde wá ránṣẹ́ ẹkú-ara-fẹ-ra-kù sí ìdílé àti mọ̀lẹ́bí olóògbé, ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re, Ìjọba àti àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ogun pẹ̀lú gbogbo ènìyàn Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà pátá.

Olóyè Ayọ Adebanjọ lo dágbére fún ayé yìí ni ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Kejì ọdún yìí (14/02/2025) ní ẹni ọdún Mẹ́rìndínlọ́gọ̀rún (96).

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Comments are closed.

button