Mínísítà Ètò Ìlera àti Àlàáfíà Ọmọnìyàn, Ọ̀jọ̀gbọ̀n Muhammed Ali Pate ti sàlàyé ipa ribiribi ti ìjọba ńkó lahti rí i dájú pe ètò ìlera tí ó yanjú wà fún ọmọ Naijiria
Ó sọ ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń ba àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìdádúró owó ìrànwọ̀ ilẹ̀ òkèèrè, àtipé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ń gbáradì fún irúfẹ́ ìsẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ síwájú kí ìjọba Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó kéde ìdádúró owó ìrànwọ́ náà
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dáwọ́ ìrànwọ́ náà dúró, mínísítà ètò ìlera fi ìdùnnú rẹ hàn sí Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fún ìrànlọ́wọ́ àti àdúrótì ọlọ́jọ pípẹ́ tí ó ti ń wáyé èyí tí ó ti kó ipa málegbàgbé fún ìdàgbàsókè ètò ìlera ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà