Ààrẹ Tinubu Buwọ́lu Gbígba Àwọn Akọ́ṣẹ́mọsẹ́ Elétò Ìlera Láti Sàmójútó Ọgbà Ìsàtúnṣe Ọmọnìyàn
Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Bọla Ahmed Tinubu ti buwọ́lu ìgbanisíṣẹ́ àwọn dókítà akọ́ṣẹ́mosẹ́ elétò ìlera àádọ́ta àti àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn tí ó tó ọgọ́rùn-un fún àmójútó ètò ìlera àwọn tí ó wà nínú Ile Ìsàtúnṣe Ọmọnìyàn gbogbo jákè jádò Orílẹ̀-èdè
Mínísítà Ọ̀rọ̀ Abẹ́lé, Ọ̀mọ̀wé Olubunmi Tunji-Ojo tún gba ìbuwọ́lù ìjọba láti jẹ́ kí àwọn alákòsóo àgùnbánirọ̀ fí àwọn àkẹ́kọ̀ọ́jáde akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ètò ìlera ráńṣẹ́ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ìtọ́jú àwọn tí ó wà nínú Ile isatunṣe ọmọniyan
Ó tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìkéde àfikún ọjọ́ ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ fún àwọn dókítà onímọ̀ ìsègùn tí ó ń siṣẹ́ lọ́wọ́ lójúnà àti dí àwọn ààyè tí ó sófo ní ẹka ìlera àjọ náà. Àtipé láìpé jọjọ, ẹka ètò ìlera yóò ní òsìṣẹ́ ní ànító àti ànísẹ́kù