Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Aṣojú Ìjọba Ilẹ̀ Áfíríkà Kẹ́dùn Olóògbé Nujoma Pẹ̀lú Nàmíbíà

Lekan Orenuga

228

Ìgbìmọ̀ Àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè Áfíríkà tí darapọ̀ mọ́ àwọn yòókù lágbayé láti ṣọfọ ikú Sam Nujoma, Ààrẹ àkọkọ́ ní Orílẹ̀-èdè Namibia lẹyìn òmìnira, tó kú ní ẹní odún márún dín lọgọ́rùn (95).

‎ Nujoma jẹ́ olókìkí ajá-fẹtọ́-ọmọnìyàn, alátakò ẹlẹyamẹya, àti olóṣèlú tó kó ipá pàtàkì l’ójúnà látí gbá òmìnira fún Orílẹ̀-èdè Namibia látí ọwọ́ ìjọba South Africa.

‎ Gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ àkọkọ́ tí Namibia, Nujoma ṣé àkóso sáà mẹ́ta látí 1990 sí 2005, bó ṣé darí orílẹ-èdè náà títí dì ìjọba tiwa-n-tiwa.

‎ Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà náà tún kẹ́dùn pẹ̀lú Ìjọba Namibia, láti ẹnu Mínísítà fún Ọrọ òkèèrè, Ambassador Yusuf Tuggar, tó ṣàpèjúwe Nujoma gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tó gá jùlọ nínú ìjà òmìnira àti ìṣọ̀kan fún ilẹ̀ Áfíríkà.

‎ Ìgbìmọ̀ tí Àwọn aṣojú ilẹ̀ Áfíríkà ṣé ìtùnú rẹ̀ sí ìjọba àti àwọn ènìyàn Namibia, àti ìdílé Nujoma.

Comments are closed.

button