Ìjọba Orílẹ̀-èdè Libya ti rí òkú àwọn arìnrìnàjò Àádọ̀ta ni ọ̀sẹ̀ yìí nínú ibojì méjì ọ̀lọ́pọ̀ èniyàn ni aginjù aṣálẹ̀ gúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè bi àwọn òṣìṣẹ́ se sọ.
Ọ̀kàndínlógún òkú ni wọ́n rí ní ọjọ́ Ẹtì ní oko kan ni ìlú Kufra.
Àwọn aláṣẹ fi sórí ẹ̀rọ ayélujára Facebook níbi ti wọ́n ti se àfihàn àwọn olópàá ati àwọn òṣìṣẹ́ ìlera tí wọ́n ń gbẹ́ ilẹ̀ ti won ṣì n kò oku àwọn ènìyàn jáde ti wọn fi asọ wé.
Ibojì àwọn arinrinajo to n káàkiri lati orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn wọ́pọ̀ ni orílẹ̀-èdè Libya.
Ní ọdún tó kojá, àwọn aláṣẹ wa òkú wọn tò tó àrùndínláàdọ̀rin jáde nínu ilẹ̀ ni agbègbè Shuayrif gúsù olu ilu,Tripoli.
Libya jẹ́ ọ̀nà gbógì ti àwọn arìnrìnàjò láti ilẹ̀ Adúláwọ̀ ati àárín ìlà oòrùn-Middle East fẹ́ràn láti máa gba lọ sí Yúrópùù. Àwọn ènìyàn tó n se fàyàwọ́ ènìyàn fún okòwò a máà ko àwọn ènìyàn yìí tó kúrò láti orílè èdè kan lọ sí òmíràn láti ibodè orilẹ-ede bíi; Chad, Niger, Sudan Egypt, Algeria àti Tunisia.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san