Ikọ̀ Akwa United ba ẹtì àilèborí ni ìgbà mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ jẹ́ nípa gbígbo ewúro sójú ikọ̀ Enyimba FC pẹ̀lú ayò méjì si oókan (2-1) ni pápá isere Godswill Akpabio International ní ilu Uyo, ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ní ọjọ́ Àìkú.
Jacob Ogunleye ló kọ́kọ́ dá àwọ̀n lu ní iṣẹ́jú mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n fún wọn ki Issah Mohammed tó dáa padà fún ikọ̀ Enyimba nígbà tó ku ìṣẹ́jú mẹ́fà kí abala àkọ́kọ́ tó parí.
Uche Sabastine ló wá fi ọba lée tí ayò fi parí sí méjì si oókan(2-1) fún ikọ̀ tó gbàlejò.
Ni pápá isere Adokiye Amiesimaka, ilu Port Harcourt, ikọ̀ Rivers United kó pàsán ẹyọkan (1-0) bo ikọ̀ Lobi Stars ti wọn kò sì leè rú túú.Timothy Zechariah
ló gbá bọ́ọ̀lù náà wọlè. Àkókò ti ikọ̀ Finidi George yóò bórí ni èyí nínú ìfagagbága mẹ́fà.
Bí àbáyọrí ayò ọjọ́ Àìkú ti NPFL se lọ nìyí:
Niger Tornadoes, Oókan sí oókan (1-1) Plateau United
Abia Warriors, Ẹẹ́ta si odo (3-0) Sunshine Stars
Bayelsa United, Oodo sí Oodo (0-0) Rangers International
Rivers United, Oókan sí oódo (1-0) Lobi Stars
Akwa United, eéji sí oókan (2-1) Enyimba
Ikorodu City, eéji sí oókan (2-1) Kwara United
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
see