Take a fresh look at your lifestyle.

Áfíríkà Kí Ifè Ẹ̀yẹ Àgbáyé Káàbọ̀

Lekan Orenuga

126

Bó tí kú oṣù díẹ̀ tí ìdíje àgbáyé àwọn ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù yóò fí wáyé ní orílẹ̀-ẹ̀dẹ̀ Amẹ́ríkà, Áfíríkà gbàlejò ifè túntún náà.

‎Ẹgbẹ́ agbabọọlu méjìlélọ́gbọ̀n 32 ní yóó kópa nínú ìdíje túntún náà níbí tí ẹgbẹ́ àgbábọ́ọ̀lù mẹ́rin yóò tí dije fún Áfíríkà. Awọn ẹgbẹ́ náà ní Al Ahly SC (Egipti), Espérance Sportive de Tunis (Tunisia), Mamelodi Sundowns (South Africa) ati Wydad AC (Morocco) láàárín ọjọ́ kẹrinla Oṣù Kẹfà ( June 14th) sí ọjọ́ kẹtala oṣù Keje (July 13th) Ọdún yìí.

‎Oludari ẹgbẹ́ Mamelodi Sundowns tí Orílẹ̀-èdè South Africa, Tlhopie Motsepe ló ṣé itẹwọgba ifè náà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀.

‎ Ifè náà yóò tẹ̀síwájú nínú ìrìn-àjò rẹ̀ ní Áfíríkà, lọ́ sí Cairo, Egypt ní ọjọ́ Àjé, ṣáájú kó tó lọ́ sí Tunisia àti Morocco níbití ES Tunis àti Wydad AC yóò gbá lalejo ní ṣisẹ-n-tẹle.

Comments are closed.

button