Àwọn alájọṣepọ̀ ààrẹ Benin fi ẹ̀wọ̀n ogún ọdún gbára lórí ìgbèrò ìfipá gbàjọba
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àwọn arákùnrin méjì kan tí wọ́n súnmọ́ ààrẹ orílẹ̀ – èdè Benin, ti fi ẹ̀wọ̀n ogún ọdún gbára lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n mú wọn lọ́dún tó kọjá lórí ìgbèrò ìfipá gbàjọba lórílẹ̀ èdè náà.
Ile Ẹjọ ti n risi ẹṣẹ inawo ati jagidijagan ni olu ilu, Cotonou ti fi ẹsun“ iwa iditẹ mọ awọn eleto aabo orilẹ ede“ ati “iwa iba oṣiṣẹ ijọba jẹ“ kan Olivier Boko, oniṣowo ti o tun jẹ ọrẹ igba pipẹ fun aarẹ Patrice Talon, ati Oswald Homeky, ti o fi igba kan jẹ Minisita fun Eto Idaraya rí.
Wọn mu awọn arakunrin mejeeji yii ni osu kẹsan an, lẹyin ti wọn fi ẹsun fifun adari eto aabo aarẹ ni owo ẹyin ki o le tẹsiwaju lori ifipagbajọba.
Gẹgẹ bi Elonm Mario Metonou, olupẹjọ pataki fun ile ejọ ti n risi ẹsun Inawo ati jagidijagan ni Benin, ṣe sọ, o ni wọn gba Homeky mu lasiko ti o n gbe apo ti wọn di owo si ti o ju mẹfa lọ fun adari eto ẹsọ aarẹ.
Lasiko ijẹjọ naa, adari eto ẹsọ aarẹ, Ajagun Djimon Dieudonné Tevoedjre, ṣalaye pe Homeky wa ri oun tẹlẹ ninu oṣu kẹsan an pe ki oun da ifipa gbajọba lọwọ Talon silẹ.
Wọn fi ẹsun ajọgbero ifipa gbajọba kan Boko, ti gbogbo eniyan ri ni “ọwọ ọtun Talon”, ti wọn si da mu lọtọ.
O ti ni erongba lati dije fun ipo aarẹ ninu ọdun 2026.
Wọn fi ẹsun kan naa kan ẹnikẹta, Rock Nieri, ti o jẹ ana Boko, laitii ri.
Lẹyin ti wọn tun yan lọdun mẹta sẹyin, Ọgbeni Talon pinnu pe oun ko ni gbero saa kẹta ni ọdun 2026.
Ofin Benin ko faaye gba ju saa muji lọ fun ipo aarẹ.
Lẹyin ẹwọn ogun ọdun ti wọn yoo fi gbara, ile ẹjọ yii tun paa laṣẹ pe ki awọn arakunrin mẹta yii o san iye owo ọgọta biliọnu CFA (miliọnu marun- din- lọgọrun dọla) fun aburu ti wọn fa si orilẹ- ede Benin.
Wọn yoo tun da san iye owo biliọnu mẹrin aabọ CFA (miliọnu mẹfa ati aabọ dọla) fun eni kọọkan.