Orílẹ̀-èdè France ti jọwọ Ibùdó Ológun rẹ̀ tó kẹ́yìn ní Orílẹ̀-èdè olómìnira Chad sílẹ̀, ibùdó Kossei ní N’Djamena. Oṣù méjì lẹ́yìn ti ilẹ̀ Chad sokùn àdéhùn ààbò le dain-dain pẹ̀lú ilẹ̀ Paris.
Bó tilẹ̀jẹ́pé ilẹ̀ Chad ló kéde òpin ìpínyà ààbò, èròngbà ìgbékalẹ̀ ki se láti ọwọ́ ilẹ̀ France nìkan bí Olùdarí ọmọ-ogun ilẹ̀ France/Áfríkà se sọ.
Kí àdéhùn náà to parí, ilẹ̀ France ti ni àwọn ènìyàn bíi ẹgbẹ̀rún ní Ilẹ̀ Chad
Lẹ́yìn ìdìgbòlùjà pẹ̀lú alákatakítí ẹ̀sìn Ìsìláàmù pẹ̀lú ọmọ ogun agbègbè, wọn ti lé ọmọ ogun French kúrò ni orílẹ̀-èdè Mali, Niger àti Burkina Faso.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san