Ààrẹ àjọ Nigeria Hockey Federation (NHF), Simon Nkom ti sọ pé ó dá òun lójú bí àdá pé ikọ̀ tó ń sojú wa ni ìdíje ọdún 2025 Africa Cup for Club Championship (ACCC) ni ilẹ̀ Ẹ́gípìtì, yóò ṣe àseyè tí alákàn ń sepo.
Ọgbẹni Nkom sọ eyi ni Abuja nígbà to n ki àwọn iko to nkopa nibi idije wipe oun gbagbọ pé orílẹ̀-èdè yìí yóò gba ife ẹ̀yẹ.
Ó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ awọn ikọ̀ tó ń kópa àti àwọn ọ̀gá wọn.
” Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ awọn ikọ̀ to wa lati ìpínlẹ̀ to n soju wa nibi idije hockey to n lọ lọwọ. Ìpínlẹ̀ bii Delta, Plateau, Niger ati Kaduna,” Nkom sọ eyi. Ikọ̀ Kaduna wuni lori jọjọ, ikọ̀ obìnrin wọn ti bori ni ìgba meje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti gbadé ìdíje super leagues, àwọn ọkùnrin wọn náà kò gbẹ́yìn nípa gbigba Liigi ni ìgbà mẹ́rin.
Ikọ̀ marun yóò soju orilẹ-ede yìí, awọn ni
Delta Queens, Kada Queens ti Kaduna àti Plateau Queens ti ilu Jos ni ipele ti àwọn Obìnrin. Kada Stars ti Kaduna àti Niger Flickers ti Minna ni ipele ti àwọn ọkùnrin
Ìdíje náà ni ìrètí wa pé yóò bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kínní yóò ṣì tẹnu bọpo ni ọjọ́ keje oṣù Kejì ọdún 2025 ni olu ìlú Ẹ́gípìtì tii se Cairo.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san