Àjọ Ọmọ Ogun ti Orílẹ̀-èdè DR Congo ti ń gbìyànjú láti dáàbò bo ará ìlú nígbà tí àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ fìdí múlẹ̀ ní ìlú Goma, ní Ọjọ́ Ẹtì, èyí tí ó dá ìfòyà, wàhálà sílẹ̀ ní àgbègbè náà
Ìbẹ̀rù-bojo ní àwọn ènìyàn àgbègbè náà wà, nígbà tí àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ gba ìsàkóso ìlú naa, èyí tí kò ju kìlómítà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n lọ sí olú ìlú Orílẹ̀-èdè náà
Ìkéde ikú ọ̀gágun Peter Cirimwami tí ó jẹ́ Gomina àgbègbè Kivu ni ó tún bu epo sí wàhálà náà, èyí tí ìròyìn fi yéwa pé, ó fi arapa níbi rògbòdìyàn náà ní Ọjọ́bọ̀, ó sì papòdà ní Ọjọ́ Ẹtì. Èyí tí ó dá ìpayà sílẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn ìlú Goma