Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ Òsèlú Democratic Alliance Gbé Pẹ́rẹ́gi Ìjà Kaná Pẹ̀lú Ìjọba Orílẹ̀-èdè South Africa

78

Ẹgbẹ́ òsèlú DA ti fi ojú ìjà hàn sí ìjọba tí ó wà lóde látàrí bí ìjọba se kùnà láti kó àkóyawọ́ èyí tí yóò fún gbogbo ẹgbẹ́ òsèlú láyè láti dásí ètò ìsèjọba, papàájùlọ nípa ètò ìlera àti ọ̀rọ̀ ilẹ̀ tí ó ń lọ lọ́wọ́ ní Orílẹ̀-èdè náà

 

Ẹgbẹ́ òsèlú DA, tí ó jẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú tí ó wà ní ipòkejì nínú ìsèjọba pè fún àtúnṣe ní kíákíá fún ìsèjọba tí ó dúró déédé, èyí tí yóò mú ìdàgbàsókè aláìlẹ́gbẹ́ bá àwùjọ

 

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Ààrẹ Orílẹ̀-èdè náà, Cyril Ramaphosa, ti fi ìgbáradì rẹ hàn láti pèpè fún ìfikùnlukù, èyí tí yóò se àtúnṣe wàhálà náà

 

 

Comments are closed.

button