Olùdarí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó, Aṣòfin Mojisola Meranda fi múlẹ̀ ní ọjọ́ Ẹtì, (Friday) tí í ṣe ọjọ́ àkọ́kọ́, tí yóò dárí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin náà gẹ́gẹ́ bí Olùdarí Ilé náà lẹ́yìn tí wọ́n ti yọ, olùdarí àná, pé òun yóò ṣe ìjọba dáradára pẹ̀lú òtítọ́ inú.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú Ilé náà, Aṣòfin Meranda sọ pé Ilé Aṣòfin náà yóò fọwọ́ sowópọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹ̀ka Ìjọba tó kú láti pèsè èrè ijoba tiwantiwa fún àwọn ará ìlú. Ó ní:
“Gbogbo ipá ni máa sà láti rí i dájú pé mo tẹ̀lé ìlànà òdodo, ìṣàkóso ìjọba rere àti ìwà ọmọlúwàbí tí wọ́n mọ ilé Aṣòfin yìí mọ́
” Lónìí, mo fẹ́ ká tún ránra wa létí ojúṣe wá gẹ́gẹ́ bí Aṣòfin tí à ń ṣojú fún àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Èkó tí wọ́n dìbò yàn wá sípò láti fi ọkàn wọn àti èrò ọkàn wọn hàn, a sì gbọ́dọ̀ làkàkà láti ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n gbé lé wa lọ́wọ́
“Bí a ṣe wá bẹ̀rẹ̀ sáà tuntun yìí nínú Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin yìí, mo fi dá yin lójú pé, ìṣàkóso yìí ṣiṣẹ́ papọ̀ fún ọjọ́ iwájú rere.
“A ó sì fọwọ́ sowópọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹ̀ka Ìjọba yòókù láti lè pèsè èrè ìjọba tiwantiwa fún àwọn ará ìlú, gẹ́gẹ́ bí àwọn tó jẹ wá lógún
“Fún ìdí èyí, a ó ṣiṣẹ́ lójúnà tí olúkúlùkù láì fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ẹ̀kọ́, ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí ẹ̀yà ṣe, àwọn olórí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ̀ yóò lé sọ pé àwọn náà kópa nínú ìṣàkóso yìí
“Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹ̀ka Ìjọba tó kù ṣe pàtàkì láti fún ìlọsíwájú bá ìṣàkóso ìjọba àti ìdàgbàsókè ìjọba tiwantiwa
“Láti wá ní àṣeyọrí èyí, a ó ní ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ẹ̀ka Ìjọba Amúṣẹ́ṣe, lábẹ́ Gómìnà, pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tó yẹ fúnra ẹni
“Nípa ṣíṣe èyí, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé, iṣẹ́ Aṣòfin wá ní àfojúsùn kan pẹ̀lú titi Ẹ̀ka Ìjọba Amúṣẹ́ṣe, kí á lé fi iṣẹ́ rere sílẹ̀ tí a bá kúrò nípò”.
Bákan náà ni Olùdarí Ilé Aṣòfin náà kéde àwọn olóyè ilé mìíràn. Àwọn náà ní: Aṣòfin Tèmítọ́pẹ́ Adédèjì gẹ́gẹ́ bí Olórí Ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tó pọ̀jú lọ nínú Ilé Aṣòfin náà, Aṣòfin Richard Kasunmu gẹ́gẹ́ bí Ìgbákejì Olórí Ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú tó pọ̀jú lọ, Aṣòfin Setonji David gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́pàá Ilé nígbà tí Aṣòfin Sanni Babátúndé di ìgbákejì Ọlọ́pàá Ilé.
Lánre Lágada-Àbáyọ̀mí