Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger, Mohammed Bago ti sí àwọn èrò Amunawa to wọn ṣe sí ìjọba ìbílẹ̀ Paikoro.
Èrò Amunawa yìí ni ọgbẹni Umar Nasiru tó jẹ aṣojú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ṣe atilẹyin fún.
Wọn ṣe iṣẹ naa láti rí wí pé àwọn agbègbè wa ni irẹpọ àti nínú imọlẹ àwọn agbègbè bí Barikiahi kopango àti wambe
Gómìnà Bago gbóríyìn fún aṣojú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin fún atilẹyin rẹ àti àpẹrẹ réré to n fi le’lẹ gẹgẹ bí adarí ilé réré.
Ó ṣe àpèjúwe rẹ gẹgẹbi aṣojú to n ṣe mú yangan láwùjọ.
Ó wá fi àsìkò náà rọ àwọn ènìyàn láti lò èrò náà ni ọna ti o tọ́ fún ìdàgbàsókè gbogbo ènìyàn