Ikọ̀ Obìnrin Cricket Nàìjíríà tí ọjọ́ orí wọn kò tó ogún ọdún-Junior Female Yellow Greens ti lu àwọn akẹgbẹ́ wọn (Scotland) ni àlùbomi pẹ̀lú wicket méje (7 wickets) níbi ìdíje ìgbáradì Cricket àgbáyé-International Cricket Council (ICC) Under-19 Women’s World Cup.
Àjọ ICC ló se àgbékalẹ̀ ìdíje náà tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ni Malaysia fún ìgbáradì àwọn akópa láti ní ìrírí.
Ìgbájú ìgbámú méje ti wọ́n fi lu ikọ̀ Scotland yóò jẹ́ kí ikọ̀ náà ní ẹ̀mí ìgboyà nígbà tí wọ́n bá ń kojú alátakò wọn, Samoa ní ọjọ́ Àbámẹ́ẹ̀a ní Ìsòrí “C” nibi ayò wọn àkọ́kọ́ ìdíle Cricket àgbáyé.
Ikọ̀ Nàìjíríà yóò tún wákò pẹ̀lú ikọ̀ New Zealand ní ogúnjọ́ oṣù yìí’ kí wọn tò wá pàdé ikọ̀ ti South Africa lẹ́yìn ọjọ́ méjì níbi ìdíje oníkọ̀ mẹ́rìndínlógún ti yóò parí ní ọjọ́ Kejì, oṣù Kejì ọdún 2025.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san.