Orílẹ̀-èdè Senegal ati Mauritania ti ní àseyọrí aláìlẹ́gbẹ́ nígbà tí wọ́n darapọ̀ mọ́ awọn akẹgbẹ wọn ní àgbáyé gẹ́gẹ́ bi olùpèsè afẹ́fẹ́ Gáàsì èyí tí ó ń wáyé láàrin ẹnu ibodè Orílẹ̀-èdè méjéèjì náà
Ilé isẹ́ ńlá kan láti Orílẹ̀-èdè Britain tí o ́wà lára àwọn tí ó dòwòpọ̀ pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè méjéèjì náà sàlàyé pe isẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu ní gbọ̀ngàn kàǹga afẹ́fẹ́ gáàsì náà
Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí ìgbésẹ̀ náà wáyé ni ó wá sí ìmúsẹ, èyí tí mínísítà ọ̀rọ̀ epo rọ̀bì Orílẹ-ede Senegal sàpèjúwe gẹgẹ bi aseyọri nla