Take a fresh look at your lifestyle.

Kémi Séba Kéde Èròńgbà Rẹ̀ Láti Díje Sí Ipò Ààrẹ Ní Ọdún 2026

135

Ajà-fẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn, Stellio Gilles Robert Capo-Chichi, ti gbogbo ayé mọ̀ sí Kémi Séba ti kéde èròńgbà rẹ̀ láti díje sí ipò ààrẹ ní Orílẹ̀-èdè Benin, èyí tí ìrètí wà pé yóò wáyé ní osù kẹrin ọdún 2026

 

Nínú fán-án-rán fídíò ìsẹ́jú mẹ́wàá tí ó jáde lórí ìkànnì ayélujára rẹ̀ ní ọjọ́ karùn-ún osù kíní, Séba fí àìdùnnú ọkàn hàn látàrí ìsèjọba ààrẹ Patrice Talon. Ó sàlàyé ipalara ti Aarẹ n ko ba ètò ọrọ̀ ajé abẹ́lé Orílẹ̀-èdè náà eyi ti o n fun awọn olùdókóòwò ilẹ̀ òkèèrè ní ànfààní tí ó pọ̀ jọjọ

 

Ó sàfihan ìgbáradì rẹ, ìlànà ètò ìjọba tí ó múná dóko, ó wá bẹ̀bẹ̀ àtìlẹyìn lọ́wọ̀ awọn ọmọ Orilẹ-ede naa ki erongba rẹ le è wa si ìmúsẹ

 

Comments are closed.

button