Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kebbi Sàgbékalẹ̀ Owó Ribiribi Fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Ọgọ́rùn-ún Tí Ó Wà Ní Yunifásitì, Orílẹ̀-èdè India

98

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kebbi, Ilà Oòrùn Àréwá, Nasir Idris ti buwọ́lu ẹgbẹ̀ta mílíọ̀nù dín díẹ̀ (N585m) fún sísan owó ilé ìwé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọgọ́rùn-ún tí wọ́n wà ní Yunifásitì ní Orílẹ̀-èdè India

 

Ìgbésẹ̀ náà sàfihàn ìpinnu Gómìnà Idris láti mú ìdàgbàsókè bá ètò ẹ̀kọ́ àti ìdàgbàsókè àwùjọ

 

Gẹ́gẹ́ bí Kọmísọ́nà ètò Ẹ̀kọ́, Alhaji Isah Abubakar Tunga se sàlàyé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ, Dókítà àti ìmọ̀ ètò ìlera. Síwájú si, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n míràn wà ní Orílẹ̀-èdè Egypt pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Kebbi àti ìjọba Orílẹ̀-èdè Egypt

 

Comments are closed.

button