Ògúnná Gbòǹgbò Kan Nínú Ẹgbẹ́ Òsèlú PDP Se Ìtorẹ Àánú Fún Àwọn Ògo Wẹẹrẹ Ní Ìpínlẹ̀ Sokoto
Èèkàn kan nínú ẹgbẹ́ òsèlú PDP ẹka ti ìpínlẹ̀ Sokoto, Alhaji Faruku Sarkin Fada ti gbáradì láti se ètò dídábẹ́ fún àwọn ògo wẹẹrẹ tí kò dín ní ẹgbẹ̀rún kan ní ìjoba ìbílẹ̀ méjì, ní Ìpínlẹ̀ Sokoto
Kété lẹ́yìn ìfilọ́lẹ̀ ètò náà, agbátẹrù ètò náà sàlàyé pé, ìgbésẹ̀ náà wáyé láti se ìdẹ̀kùn fún àwọn ènìyàn rẹ àti láti mójútó ìgbáyégbádùn wọn
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ, alaga ẹgbẹ PDP ti ìpínlẹ̀ Sokoto, Bello Muhammad Goronyo lu agbátẹrù ètò náà lọ́gọ ẹnu fún iṣẹ́ olóore náà. O wa rọ awọn ti Ọlọrun sẹ́gi ọlà fún láwùjo láti kọ́se irúfẹ́ iṣẹ́ ìdàgbàsókè náà