Kò dín ní igba ènìyàn nínú àwọn olùgbé Abakpa, àgbègbè Enugu tí ó jẹ ànfààní ìwòsàn ọ̀fẹ́, èyí tí àjọ NAFOWA, tí ó jẹ́ àkójọ ìyàwó àwọn ọmọ ogun òfurufú, tí wọ́n se agbátẹrù rẹ̀
Ètò náà dá lórí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa ètò ìlera, ìtọ́jú eyín , ojú, òògùn ọ̀fẹ́ àti pínpín àpò ẹ̀fọn fún àwọn ènìyàn àgbègbè náà
Ìfilọ́lẹ̀ ètò náà wáyé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, níbi tí ààrẹ àpapọ̀ àjọ náà, Ọ̀mọ̀wé Rakiya Abubakar ti sọ pe ìgbésẹ̀ náà wáyé láti tán ìsòro àìrajaja ètò ìlera. Ó wá rọ àwọn ènìyàn àgbègbè náà láti lo ànfààní náà fun idagbasoke ilera wọn