Olùbádámòràn Pàtàkì Sí Gómìnà Umar Namadi, Malam Isa Surajo sọ wipe ẹka ètò ìlera ìpínlẹ̀ Jigawa nílò àtúntò tí ó múná dóko, èyí tí yóò mú kí ètò ìlera di ìrọ̀rùn fún mùtú-mùwà ní ìpínlẹ̀ náa
Ó sọ ọ̀rọ̀ naa fún àwọn oníròyìn ní ìlú Èkó níbi ayẹyẹ ìfúnni ní àmì ẹ̀yẹ, eyi ti o waye latari ìperegedé nípa ètò àbò àti ọ̀gbìn, ti wọn fun Gomina Umar Namadi
Gẹ́gẹ́ bí ó se sọ, ìgbìyànjú gómìnà láti mú ìgbòòrò bá ètò ìlera àti ìgbáyégbádùn àwọn ará ìlú ni ó mú kí ó gba awọn oṣisẹ elétò ìlera ẹgbẹ̀rún mẹ́ta. Ireti wa pe igbesẹ naa yoo mu idagbasoke ba eto ìlera alábọ́dé, ipese eto ilera ti o peye ati ìdènà ikú àìròtẹ́lẹ̀ ní àwùjọ