Ìjọba àpapọ̀ ti sàlàyé pàtàkì rírà àti bíbu ọlá fún àwọn ohun èlò tiwa-n-tiwa, lójúnà àti mú ìdàgbàsókè bá ètò ọrọ̀ ajé Orílẹ̀-èdè Naijiria
Ìpè náà wáyé láti ọ́ọ́fìsì akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ níbi àpérò kan ti o waye láti mú ìgbéga bá awọn ohun elo ti a pèsè lábẹ́lé àti láti gbé ìgbésẹ̀ akin èyí tí yóò mú ìgbòòrò ba eto ọrọ aje, àti ìsàkójọ ọgbọ́n ti yoo mu ìlọsíwájú bá àwọn ohun èlò tí a pèsè ní Orílẹ̀-ede Naijiria
Agbátẹrù ètò naa, George Nwabueze salaye pe, igbesẹ naa se pataki lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje léyìí tí yóò sọ ayé di gbẹdẹmukẹ fun mùtú-mùwà. O wa parọwa si gbogbo ọmọ Orilẹ-ede lati máse fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn ohun elo ti a pese lábẹ́lé, fun idagbasoke Orilẹ-ede Naijiria