Take a fresh look at your lifestyle.

Àtìlẹyìn Aláìlẹ́gbẹ́ Ni Ààrẹ Tinubu Ṣe Lójúnà Àti Mú Àtúntò Bá Àjọ Tí Ó Ń Rí Sí Ìwọlé-Jáde Ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà- Mínísítà Sọ̀rọ̀ Pẹ̀lú Àrídájú

157

Mínísítà Fún Ọ̀rọ̀ Abẹ́lé, Ọ̀mọ̀weh Olubunmi Tunji-Ojo ti lu Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu lọ́gọ ẹnu fún àtìlẹyìn rẹ̀ lójúnà àti jẹ́ kí àjọ tí ó ń rí sí ìwọlé-jáde ní Orílẹ̀-èdè Naijiria se àseyorí

 

Ọ̀rọ̀ náà jẹ jáde níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó wáyé ní ìlú Abuja, níbi tí mínísítà ti sàfihàn àwọn àseyorí àjọ náà èyí tí ó wáyé látàrí àtìlẹyìn, ìmọ̀ràn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ààrẹ

 

Mínísítà fi àrídájú hàn pé àjọ náà yóò tẹ̀síwájú nínú ìlàkààkà àti iṣẹ́ takuntakun rẹ, ó wá sàfihàn pàtàkì àmójútó ìgbáyégbádùn àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà èyí tí yóò fun wọn ni anfaani lati se iṣẹ́ dé ògóńgó

Comments are closed.

button