Olórí Orilẹ Èdè, Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti kéde ikú Ọga àgbà ọmọ ogun Orilẹ Èdè Nàìjíríà ẹni tó di oloogbe ni ẹni ọdún Merindinlọgọta (56).
George Olayinka Akintola
Olórí Orilẹ Èdè, Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti kéde ikú Ọga àgbà ọmọ ogun Orilẹ Èdè Nàìjíríà, Taoreed Abiodun Lagbaja, ẹni tó di oloogbe ni ẹni ọdún Merindinlọgọta (56).
Lagbaja, ẹni tí wọn bí ní ọjọ́ Kejidinlọgbọn oṣù Kejì, Ọdún 1968 (28/02/1978), ti Ààrẹ Tinubu si yan sípò gẹ́gẹ́ bíi olórí ọmọ ogún Orilẹ Èdè Nàìjíríà ní ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kẹfà ọdún 2023 (19/06/3023) náà ló jẹ Ọlọrun n’ipe ní ìlú Èkó, ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun tíì ṣe ọjọ́ Kàrún oṣù Kọkànlá, Ọdún 2024 lẹ́yìn àìsàn ránpẹ́.
O bẹrẹ iṣẹ ìríjú rẹ nígbà tó wolé sí ilé ẹkọ Nigerian Defence Academy ni ọdún 1987. O di igbakeji ọmọ ogun ori ilẹ gẹgẹ bíi ẹgbẹ ọmọ ogun Kokandinlogoji ni oṣù Kẹsan ọdún 1992.
Ni gbogbo asiko to fi ṣíṣẹ, ọgagun Lágbájá se afihan adari rere tó ní èmi ifọkansin, nígbà tó jẹ aláṣẹ ọ̀wọ́ Ketalelaadorun (93 Battalion) àti ọ̀wọ́ Kejilelaadorin (72 Special Forces Battalion).
O ṣiṣẹ takuntakun nínú ẹka ìpèsè ààbò nínú èyí ti a ti rí (Operation ZAKI) ni Ìpínlẹ̀ Benue, Lafiya Soke ni Ìpínlẹ̀ Borno, Ufoka ni Gúsù Ìlà Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà, ati (Operation Forest Sanity) jákèjádò Ìpínlẹ̀ Kaduna ati Niger.
O jẹ akeko jáde ní ilé ẹkọ ológun ni Ilẹ America (U.S Army War College) níbi tó ti gba oye ijinlẹ (M.Sc Starategic Studies) nínú èyí to mu kí o yege nínú ìmọ̀ nípa ìdàgbàsókè nípa bí a ṣe n dari ile iṣẹ ológun.
Ìyàwó àti àwọn ọmọ méjì ní Ogagun Lagbaja fi sílẹ s’aye.
Ààrẹ Tinubu fi iṣẹ́ ibani kẹ́dùn ránṣẹ́ sí ẹbí àti Ilé iṣẹ́ Ológun, nígbà tó gbàdúrà kí Olorun tẹ Ogagun Lagbaja sí afẹ́fẹ́ rere.
George Olayinka Akintola