Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ba Ààrẹ Bọla Tinubu, Ilé Iṣẹ́ Ọmọ Ológun, àti ìjọba Ìpínlè Ọ̀ṣun kẹ́dùn ikú Ọ̀gá ọmọ ológun Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Makinde ló ti fi ikú ọga ọmọ ológun Taoreed Abiodun Lagbaja wé àdánù nlá fún Orílẹ̀ èdè yìí.
Gómìnà, ẹni tó fi Lagbaja wé ọmọ Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tòótọ́ àti ọkàn lára ọmọ ológun tó dára jù ní ilẹ yìí, lo tí kedun pẹ̀lú Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu àti gbogbo ilé iṣẹ́ ológun pátá.
Bákan náà ló bá ìdílé olóògbé Lagbaja, Ìjọba àti gbogbo ọmọ bíbí Ìpínlè Ọ̀ṣun kẹ́dùn, tó sì gbàdúrà kí Allah tẹ sí afẹ́fẹ́ rere.
Abiola Olowe
Ìbàdàn