Orilẹ̀-ède Nàìjíríà ti fi sísetán wọn hàn lati siṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Ààrẹ Asẹ̀sẹ̀yàn ẹlẹ́ẹ̀kẹtadínláàdọ̀ta orilẹ̀-ède Amẹrika, Donald Trump.
Mínísítà orilẹ-ède yíì nipa ìròyìn sọ pé, orilẹ-ède Nàìjíríà wa bákan náà pèlú orilẹ-ède yoku nipa ìkíni ati èròngbà rere ti orilẹ-ède kọ̀kan ń fẹ́ fún ilẹ̀ rẹ ati fún ile Amẹrika. O sọ èyí ni ọjọ́ Ọjọ́rú pèlú àwọn oníròyìn ni gbọ̀ngàn ilé ààrẹ lẹyìn ti wọn ti sún ọjọ Ipade igbimo FEC to yẹ ko wáyé ni Abuja síwájú.
Mínísítà náà sọ siwaju pé bi ọygbẹ́ni Donald Trump ti jáwé olúborí ninu ìbò ti o ṣẹ̀ṣẹ̀ pari yìí, orilẹ-ède Nàìjíríà ń fojú sọ́nà sí ajọṣepọ to gúnmọ́ ti wọ́n yóò ri ànfààní tó pọ̀ pẹlú ilẹ̀ Amẹrika jù ti àtẹ̀yìnwá lọ.
Ó fikun pé, ààrẹ Tinubu gbagbo ninu ìjọba àwarawa
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san