Take a fresh look at your lifestyle.

Aya Ààrẹ Kẹ́dùn Ikú Ọ̀gá Ológun, Ó bẹ Ìdílé Olóògbé Wò

68

 

Aya ààrẹ orílè-èdè yìí, Oluremi Tinubu ti fi ibanuje rẹ hàn latari ipapoda ọ̀gá àwọn ọmọ ológun tẹ́lẹ̀rí, ọ̀gágun Taoreed Lagbaja, tó kú ni alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní ilú Eko.

O sọ pé, ” pelu ibanuje ọkan ni óún se gba iroyin ibanuje iku ọgá àwọn ọmọ ológun , ọgagun Taoreed Lagbaja.

“Ki Ọlọrun oba tu àwon ìdílè rẹ ati gbogbo àwọn tó fi sílẹ lọ ninu.

Ki Olorun tẹẹ sí afẹfẹ rere”.

Obìnrin àkọkọ orilẹ̀-ède yíì bẹ ìdílé Oloogbe náà wò. Iyawo igbakeji aare,Hajia Nana Shettima ati iyawo Oludamọran pàtàkì ni ti ọrọ ààbò orilẹ-ède yíì, Hajia Zara Ribadu, ni wọn jọ kọ̀wọ́ rin, a ti ọwọ́ ìyáàfin Oghogho Musa.gbàwọ́n lálejò.

Nigbati o n ba aya oloogbe , ìyáàfin Mariya Abiodun Lagbaja sọrọ, o wipé, “Ọlọrun nikan lọ mo igba ti ẹda yóò jáde laye”. O gbawọ́n nímọ̀ràn láti máa wo iṣẹ rere ati ogún rere ti ọkọ wọn fi sílẹ lọ fun awokọṣe.

Oloogbe náà ku ni ọjọ Isẹgun, ọjọ karun ùn, osu kọkànlá ọdún yìí léyìn àìsàn ránpẹ́ ni ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì.

Olóògbé ọgagun Lagbaja sìn orilẹ̀-èdè yìí bíi ọ̀gágun àgbà láti osu kẹfà odun 2023 titi di ọjọ karùn ún, oṣù kọkànlá ọdún 2024..

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button