Gómìnà ìpínlẹ̀ Bayelsa, Douye Diri ti bẹbẹ fún àtìlẹyìn ààrẹ Bola Tinubu fún àmúlò iroyin ọ̀nà abayọ sí wàhálà ti àbàwọ́n epo n fà sí àyíká àti ìpínlè náà lápapọ̀.
Gómìnà jẹ́ ko di mímọ̀ nǹkan ti àwọn ará ìlú ń là kọja nípa wahala ìwakùsà epo àtí bi o ti kọlu ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ náà, ó so èyí ni ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni Abuja níbi àpérò kan.
Ó fé ki wọn gbá gbogbo agbègbè ti ọ̀rọ̀ kàn náà mọ́ tóní tóní. Kí ìjọba jọ̀wọ́ bàwọn tú ìlú àti gbogbo àyíká se.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san